Jeremaya 46:21-26 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Àwọn ọmọ ogun tí ó fi owó bẹ̀ lọ́wẹ̀,dàbí akọ mààlúù àbọ́pa láàrin rẹ̀;àwọn náà pẹ̀yìndà, wọ́n ti jọ sálọ,wọn kò lè dúró;nítorí ọjọ́ ìdààmú wọn ti dé bá wọn,ọjọ́ ìjìyà wọn ti pé.

22. Ó ń dún bí ejò tí ó ń sálọ;nítorí pé àwọn ọ̀tá rẹ̀ ń bọ̀ tagbára tagbára,wọ́n ń kó àáké bọ̀ wá bá a,bí àwọn tí wọn ń gé igi.

23. Wọn yóo gé igi inú igbó rẹ̀ lulẹ̀.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbó náà dí,nítorí pé igi ibẹ̀ pọ̀ bí eṣú, tí wọn kò sì lóǹkà.

24. A óo dójú ti àwọn ará Ijipti,a óo fà wọ́n lé àwọn ará ìhà àríwá lọ́wọ́.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

25. OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: “N óo fi ìyà jẹ Amoni, oriṣa Tebesi, ati Farao, ati Ijipti pẹlu àwọn oriṣa rẹ̀, ati àwọn ọba rẹ̀. N óo fìyà jẹ Farao ati àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

26. N óo fà wọ́n lé àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́; n óo fà wọ́n fún Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwọn eniyan yóo máa gbé Ijipti bíi ti àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Jeremaya 46