Jeremaya 44:28-30 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Àwọn eniyan díẹ̀ ni wọn yóo sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Ijipti lọ sí ilẹ̀ Juda. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ṣẹ́kù ní Juda, tí wọ́n lọ sí Ijipti yóo wá mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóo ṣẹ, bóyá tèmi ni, tabi tiwọn.

29. Èyí ni yóo jẹ́ àmì fun yín pé n óo jẹ yín níyà ní ilẹ̀ yìí, kí ẹ lè mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ibi tí mo sọ si yín yóo ṣẹ mọ yín lára,

30. Èmi OLUWA ni mo sọ ọ́ pé n óo fi Farao Hofira ọba Ijipti lé ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́ ati àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekaya, ọba Juda lé ọwọ́ ọ̀tá rẹ̀, Nebukadinesari, ọba Babiloni, ẹni tí ó ń wá ọ̀nà láti pa á.’ ”

Jeremaya 44