Jeremaya 44:15-20 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n mọ̀ pé àwọn iyawo wọn ń sun turari sí àwọn oriṣa ati àwọn obinrin tí wọ́n pọ̀ gbáà tí wọn wà nítòsí ibẹ̀, ati àwọn tí wọn ń gbé Patirosi ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n bá dá Jeremaya lóhùn,

16. wọ́n ní, “A kò ní fetí sì ọ̀rọ̀ tí ò ń bá wa sọ lórúkọ OLUWA.

17. Ṣugbọn a óo máa san gbogbo ẹ̀jẹ́ wa, a óo máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, oriṣa wa, a óo sì máa ta ohun mímu sílẹ̀, bí àwa ati àwọn baba ńlá wa, ati àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa ti ṣe ní gbogbo ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu; nítorí pé nígbà náà à ń jẹ oúnjẹ ní àjẹyó, ó dára fún wa, ojú wa kò sì rí ibi.

18. Ṣugbọn láti ìgbà tí a ti dáwọ́ ati máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run dúró, tí a kò sì máa ta ohun mímu sílẹ̀ mọ́, ni a kò ti ní nǹkankan mọ́, tí ogun ati ìyàn sì fẹ́ẹ̀ pa wá tán.”

19. Àwọn obinrin bá tún dáhùn pé, “Nígbà tí à ń sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ ohun mímu sí i, ṣé àwọn ọkọ wa ni kò mọ̀ pé à ń ṣe àkàrà dídùn, tí à ń ṣe bí ère rẹ̀ fún un ni, ati pé à ń ta ohun mímu sílẹ̀ fún un?”

20. Jeremaya sọ fún gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n dá a lóhùn, lọkunrin ati lobinrin pé:

Jeremaya 44