Jeremaya 33:10-14 BIBELI MIMỌ (BM)

10. OLUWA ní, “A óo tún gbọ́ ohùn ayọ̀ ati inú dídùn ninu ìlú Juda ati ìgboro Jerusalẹmu, tí ẹ sọ wí pé ó ti di ahoro, tí kò sí eniyan tabi ẹranko tó ń gbé inú wọn.

11. A óo tún gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo ati ohùn àwọn tí wọn ń kọrin bí wọ́n ti ń mú ẹbọ ọpẹ́ wá sinu ilé OLUWA wí pé: 107:1; 118:1; 136:1‘Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun,nítorí pé rere ni OLUWA,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae!’Nítorí pé n óo dá ire wọn pada bíi ti ìgbà àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

12. OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ní gbogbo ibi tí ó ti di ahoro yìí, tí eniyan tabi ẹranko kò gbé ibẹ̀, àwọn olùṣọ́-aguntan yóo sì tún máa tọ́jú àwọn agbo ẹran wọn ninu gbogbo àwọn ìlú ibẹ̀.

13. Àwọn agbo ẹran yóo tún kọjá níwájú ẹni tí ó ń kà wọ́n ninu àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè olókè, ati àwọn ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela ati àwọn ìlú tí wọn wà ní Nẹgẹbu, ní ilẹ̀ Bẹnjamini, ní agbègbè tí ó yí Jerusalẹmu ká, ati àwọn ìlú Juda. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

14. Ó ní, “Àkókò ń bọ̀, tí n óo mú ìlérí tí mo ṣe fún ilé Israẹli ati ilé Juda ṣẹ.

Jeremaya 33