Jeremaya 29:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ẹ máa wá alaafia ìlú tí mo ko yín lọ, ẹ máa gbadura sí OLUWA fún un, nítorí pé ninu alaafia rẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ti ní alaafia.

8. Nítorí èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ pé kí ẹ má jẹ́ kí àwọn wolii ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ láàrin yín tàn yín jẹ, kí ẹ má sì fetí sí àlá tí wọn ń lá;

9. nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín ní orúkọ mi, n kò rán wọn níṣẹ́.’

10. “Nígbà tí aadọrin ọdún Babiloni bá pé, n óo mójú tó ọ̀rọ̀ yín, n óo mú ìlérí mi ṣẹ fun yín, n óo sì ko yín pada sí ibí yìí.

11. Nítorí pé mo mọ èrò tí mò ń gbà si yín, èrò alaafia ni, kì í ṣe èrò ibi. N óo mú kí ọjọ́ ọ̀la dára fun yín, n óo sì fun yín ní ìrètí.

12. Ẹ óo ké pè mí, ẹ óo gbadura sí mi, n óo sì gbọ́ adura yín.

13. Ẹ óo wá mi, ẹ óo sì rí mi, bí ẹ bá fi tọkàntọkàn wá mi.

14. Ẹ óo rí mi, n óo dá ire yín pada, n óo ko yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè ati láti gbogbo ibi tí mo ti le yín lọ; n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti le yín kúrò lọ sí ìgbèkùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

15. “Nítorí ẹ wí pé, ‘OLUWA ti gbé àwọn wolii dìde fun wa ní Babiloni.’

16. Nípa ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú yìí, àní àwọn ará yín tí wọn kò ba yín lọ sí ìgbèkùn,

17. OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, ‘N óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, n óo sì ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè jẹ ẹ́.’

Jeremaya 29