Jeremaya 27:8-11 BIBELI MIMỌ (BM)

8. OLUWA ní, “Ṣugbọn bí orílẹ̀-èdè tabi ìjọba kan bá kọ̀, tí wọn kò sin Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí wọn kò sì ti ọrùn wọn bọ àjàgà rẹ̀, ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn ni n óo fi jẹ orílẹ̀-èdè náà níyà títí n óo fi fà á lé ọba Babiloni lọ́wọ́.

9. Nítorí náà, ẹ má fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wolii yín, ati àwọn awoṣẹ́ yín, àwọn alálàá yín ati àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, ati àwọn oṣó yín, tí wọn ń sọ fun yín pé ẹ kò ní di ẹrú ọba Babiloni.

10. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fun yín, wọ́n fẹ́ kí á ko yín jìnnà sí ilẹ̀ yín ni. N óo le yín jáde; ẹ óo sì ṣègbé.

11. Ṣugbọn orílẹ̀-èdè tí ó bá ti ọrùn ara rẹ̀ bọ àjàgà ọba Babiloni, tí ó sì ń sìn ín, n óo fi sílẹ̀ lórí ilẹ̀ rẹ̀, kí ó lè máa ro ó, kí ó sì máa gbé ibẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Jeremaya 27