Jeremaya 27:4-7 BIBELI MIMỌ (BM)

4. sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n sọ fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní

5. òun ni òun fi agbára ńlá òun dá ayé: ati eniyan ati ẹranko tí wọ́n wà lórí ilẹ̀; ẹni tí ó bá tọ́ lójú òun ni òun óo sì fi wọ́n fún.

6. Ó ní òun ti fún Nebukadinesari, ọba Babiloni iranṣẹ òun, ní gbogbo àwọn ilẹ̀ wọnyi, òun sì ti fún un ni àwọn ẹranko inú igbó kí wọn máa ṣe iranṣẹ rẹ̀.

7. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóo máa ṣe ẹrú òun ati ọmọ rẹ̀, ati ọmọ ọmọ rẹ̀, títí àkókò tí ilẹ̀ òun pàápàá yóo fi tó, tí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba ńláńlá yóo sì kó o lẹ́rú.”

Jeremaya 27