26. ati gbogbo àwọn ọba ilẹ̀ àríwá, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lọ́nà jíjìn. N óo sì fún àwọn ìjọba gbogbo ilẹ̀ ayé mu pẹlu. Lẹ́yìn tí gbogbo wọn bá ti mu tiwọn tán, ọba Babiloni yóo wá mu tirẹ̀.
27. OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé, “OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí ẹ mu ọtí kí ẹ yó, kí ẹ sì máa bì, ẹ ṣubú lulẹ̀ kí ẹ má dìde mọ́; nítorí ogun tí n óo jẹ́ kí ó bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin yín.
28. Bí wọn bá kọ̀ tí wọn kò gba ife náà lọ́wọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, wí fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní wọ́n gbọdọ̀ mu ún ni!
29. Nítorí pé mo ti bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ibi ṣẹlẹ̀ sórí ìlú tí à ń fi orúkọ mi pè yìí, ǹjẹ́ ẹ lè lọ láìjìyà bí? Rárá o, ẹ kò ní lọ láìjìyà nítorí pé mo ti pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ ayé kú ikú idà, èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
30. “Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí fún wọn pé:‘OLUWA yóo bú ramúramù láti òkè,yóo pariwo láti ibi mímọ́ rẹ̀.Yóo bú ramúramù mọ́ àwọn eniyan inú agbo rẹ̀.Yóo kígbe mọ́ gbogbo aráyé bí igbe àwọn tí ń tẹ àjàrà.