9. N óo mú kí wọn máa pa ọmọ wọn ọkunrin ati obinrin jẹ. Olukuluku yóo máa pa aládùúgbò rẹ̀ jẹ nítorí ìdààmú tí àwọn ọ̀tá wọn, ati àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn yóo kó bá wọn, nígbà tí ogun bá dótì wọ́n.”
10. OLUWA ní lẹ́yìn náà kí n fọ́ ìgò amọ̀ náà ní ojú àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi,
11. kí n sì sọ fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Bí ẹni fọ́ ìkòkò amọ̀ ni n óo ṣe fọ́ àwọn eniyan yìí ati ìlú yìí, kò sì ní ní àtúnṣe mọ́. Ní Tofeti ni wọn yóo máa sin òkú sí nígbà tí wọn kò bá rí ààyè sin òkú sí mọ́.
12. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe sí ìlú yìí ati àwọn tí wọn ń gbé ibẹ̀. Bíi Tofeti ni n óo ṣe ìlú náà; Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.