7. OLUWA wí pé,“Mo ti kọ ilé mi sílẹ̀;mo ti kọ ogún tí a pín fún mi sílẹ̀.Mo ti fa ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́ lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
8. Ogún mi ti dàbí kinniun inú igbó sí mi,ó ti sọ̀rọ̀ burúkú sí mi;nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.
9. Ṣé ogún mi ti dàbí ẹyẹ igún aláwọ̀ adíkálà ni?Ṣé àwọn ẹyẹ igún ṣùrù bò ó ni?Ẹ lọ pe gbogbo àwọn ẹranko igbó jọ,ẹ kó wọn wá jẹun.
10. Ọpọlọpọ àwọn darandaran ni wọ́n ti ba ọgbà àjàrà mi jẹ́,wọ́n ti tẹ oko mi mọ́lẹ̀,wọ́n sọ oko mi dáradára di aṣálẹ̀.