Jẹnẹsisi 40:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò kan, agbọ́tí Farao, ọba Ijipti, ati olórí alásè rẹ̀ ṣẹ ọba.

2. Inú bí Farao sí àwọn iranṣẹ rẹ̀ mejeeji yìí,

3. ó sì jù wọ́n sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Josẹfu wà.

4. Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fi wọ́n sábẹ́ àkóso Josẹfu, wọ́n sì wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà fún ìgbà díẹ̀.

5. Ní òru ọjọ́ kan, agbọ́tí ọba ati olórí alásè náà lá àlá kan, àlá tí olukuluku lá sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀.

Jẹnẹsisi 40