Jẹnẹsisi 3:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ejò jẹ́ alárèékérekè ju gbogbo ẹranko tí OLUWA Ọlọrun dá lọ. Ejò bi obinrin náà pé, “Ngbọ́! Ṣé nítòótọ́ ni Ọlọrun sọ pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso àwọn igi ọgbà yìí?”

2. Obinrin náà dá a lóhùn, ó ní: “A lè jẹ ninu èso àwọn igi tí wọ́n wà ninu ọgbà,

3. àfi igi tí ó wà láàrin ọgbà nìkan ni Ọlọrun ní a kò gbọdọ̀ jẹ ninu èso rẹ̀, a kò tilẹ̀ gbọdọ̀ fọwọ́ kàn án, ati pé ọjọ́ tí a bá fọwọ́ kàn án ni a óo kú.”

4. Ṣugbọn ejò náà dáhùn, ó ní, “Ẹ kò ní kú rárá,

5. Ọlọrun sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé bí ẹ bá jẹ ẹ́, ojú yín yóo là, ẹ óo sì dàbí òun alára, ẹ óo mọ ire yàtọ̀ sí ibi.”

Jẹnẹsisi 3