1. Láti ibẹ̀ ni Abrahamu ti lọ sí agbègbè Nẹgẹbu, ó sì ń gbé Gerari, ní ààrin Kadeṣi ati Ṣuri.
2. Abrahamu sọ fún àwọn ará Gerari pé arabinrin òun ni Sara aya rẹ̀, Abimeleki, ọba Gerari bá ranṣẹ lọ mú Sara.
3. Ṣugbọn Ọlọrun tọ Abimeleki wá lóru lójú àlá, ó sì wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀! Ikú ti pa ọ́ tán báyìí, nítorí pé obinrin tí o mú sọ́dọ̀, aya aláya ni.”
4. Ṣugbọn Abimeleki kò tíì bá Sara lòpọ̀ rárá, ó bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, o wá lè pa àwọn eniyan aláìṣẹ̀ bí?
5. Ṣebí ẹnu ara rẹ̀ ni ó fi sọ pé arabinrin òun ni, tí obinrin náà sì sọ pé arakunrin òun ni. Ohun tí mo ṣe tí ó di ẹ̀ṣẹ̀ yìí, òtítọ́ inú ati àìmọ̀ ni mo fi ṣe é.”