5. Abramu mú Sarai iyawo rẹ̀, ati Lọti, ọmọ arakunrin rẹ̀ lọ́wọ́ lọ, ati gbogbo ohun ìní wọn ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n jẹ́ tiwọn ní Harani. Wọ́n jáde, wọ́n gbọ̀nà ilẹ̀ Kenaani.Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Kenaani,
6. Abramu la ilẹ̀ náà kọjá lọ sí ibi igi Oaku ti More, ní Ṣekemu. Àwọn ará Kenaani ni wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà nígbà náà.
7. Nígbà náà ni OLUWA fara han Abramu, ó wí pé, “Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA tí ó fara hàn án.
8. Lẹ́yìn náà Abramu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí orí òkè tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó pàgọ́ sibẹ. Bẹtẹli wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ibùdó rẹ̀, Ai sì wà ní ìhà ìlà oòrùn. Ó tún tẹ́ pẹpẹ mìíràn níbẹ̀, ó sì sin OLUWA.