Ìwé Òwe 9:12-14 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Bí o bá gbọ́n, o óo jèrè ọgbọ́n rẹ,Bí o bá sì jẹ́ pẹ̀gànpẹ̀gàn, ìwọ nìkan ni o óo jèrè rẹ̀.

13. Aláriwo ni obinrin tí kò gbọ́n,oníwọ̀ra ni, kò sì ní ìtìjú.

14. Á máa jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀,á jókòó ní ibi tí ó ga láàrin ìlú.

Ìwé Òwe 9