Ìwé Òwe 9:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Nípasẹ̀ mi ẹ̀mí rẹ yóo gùn.Ọpọlọpọ ọdún ni o óo sì lò lórí ilẹ̀ alààyè.

12. Bí o bá gbọ́n, o óo jèrè ọgbọ́n rẹ,Bí o bá sì jẹ́ pẹ̀gànpẹ̀gàn, ìwọ nìkan ni o óo jèrè rẹ̀.

13. Aláriwo ni obinrin tí kò gbọ́n,oníwọ̀ra ni, kò sì ní ìtìjú.

14. Á máa jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀,á jókòó ní ibi tí ó ga láàrin ìlú.

15. A máa kígbe pe àwọn tí ń kọjá lọ,àwọn tí ń bá tiwọn lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn, pé,

16. “Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ̀kan, kí ó máa bọ̀!”Ó sì wí fún àwọn òmùgọ̀ pé,

17. “Omi tí eniyan bá jí mu a máa dùn,oúnjẹ tí a bá jí jẹ, oyinmọmọ ni.”

Ìwé Òwe 9