3. ó ń kígbe lóhùn rara lẹ́nu ibodè àtiwọ ìlú,ó ń ké ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pẹlu,ó ń wí pé:
4. “Ẹ̀yin eniyan ni mò ń pè,gbogbo ọmọ eniyan ni mò ń ké sí.
5. Ẹ̀yin òpè, ẹ kọ́ ọgbọ́n,ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ fetí sí òye.
6. Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ pataki ni mo fẹ́ sọ.Ohun tí ó tọ́ ni n óo sì fi ẹnu mi sọ.