Ìwé Òwe 8:22-26 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi,kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀.

23. Láti ayébáyé ni a ti yàn mí,láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá.

24. Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà,nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi.

25. Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn,kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà.

26. Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko,kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀.

Ìwé Òwe 8