31. Sibẹsibẹ, bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, yóo fi san ìlọ́po meje,ó lè jẹ́ pé gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni yóo fi san án.
32. Ẹni tí ó bá ṣe àgbèrè kò lọ́gbọ́n lórí,ẹni tí ó bá dán an wò, ara rẹ̀ ni ó ń parun.
33. Ọgbẹ́ ati àbùkù ni yóo gbà,ìtìjú rẹ̀ kò sì ní kúrò lára rẹ̀ laelae.
34. Nítorí owú jíjẹ a máa mú kí inú ọkọ ru,kò sì ní jẹ́ ṣàánú àlè bó bá di pé à ń gbẹ̀san.
35. Kò ní gba owó ìtanràn,ọpọlọpọ ẹ̀bùn kò sì ní lè tù ú lójú.