Ìwé Òwe 6:11-21 BIBELI MIMỌ (BM)

11. yóo jẹ́ kí òṣì dé bá ọ, bí ọlọ́ṣà dé bá eniyan. Àìní yóo sì dé bá ọ bíi jagunjagun dé báni.

12. Eniyan lásán, ìkà eniyan, a máa rìn káàkiri,a máa sọ̀rọ̀ àrékérekè,

13. bí ó ti ń ṣẹ́jú, bẹ́ẹ̀ ni ó ń jansẹ̀ mọ́lẹ̀,tí ó sì ń fi ìka ṣe àpèjúwe.

14. Ó ń fi inú burúkú pète ibi, ó sì ń fi ojoojumọ dá ìjà sílẹ̀,

15. nítorí náà, ibi yóo dé bá a lójijì,yóo parun kíá láìsí àtúnṣe.

16. Àwọn nǹkan mẹfa kan wà tí OLUWA kò fẹ́:wọ́n tilẹ̀ tó meje tí ó jẹ́ ohun ìríra fún un:

17. Ìgbéraga, irọ́ pípa,ẹni tí ń déédé pa aláìṣẹ̀,

18. ọkàn tí ń pète ìkà,ẹsẹ̀ tí ń sáré sí ibi,

19. ẹlẹ́rìí èké tí ẹnu rẹ̀ kún fún irọ́,ati ẹni tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin eniyan.

20. Ọmọ mi, pa òfin baba rẹ mọ́,má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.

21. Fi wọ́n sọ́kàn nígbà gbogbo,kí o sì so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.

Ìwé Òwe 6