Ìwé Òwe 5:13-19 BIBELI MIMỌ (BM)

13. N kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ min kò sì gba ti àwọn tí wọn ń tọ́ mi sọ́nà.

14. Èyí ni ó sún mi dé etí bèbè ìparun,láàrin àwùjọ eniyan.”

15. Ìwọ ọkọ, láti inú àmù rẹ ni kí o ti máa mu omi;omi tí ń sun láti inú kànga rẹ ni kí o máa mu.

16. Kò dára kí orísun rẹ máa ṣàn káàkiri,bí omi àgbàrá ní gbogbo òpópónà.

17. Tìrẹ nìkan ṣoṣo ni kí ó jẹ́,má jẹ́ kí àjèjì bá ọ pín ninu rẹ̀.

18. Jẹ́ kí orísun rẹ ní ibukun,kí inú rẹ sì máa dùn sí iyawo tí o fi àárọ̀ gbé.

19. Olólùfẹ́ rẹ tí ó dára bí abo egbin.Jẹ́ kí ẹwù rẹ̀ máa mú inú rẹ dùn nígbà gbogbo,kí ìfẹ́ rẹ̀ máa mú orí rẹ yá nígbàkúùgbà.

Ìwé Òwe 5