1. Ọmọ mi fetí sí ọgbọ́n tí mò ń kọ́ ọ,tẹ́tí rẹ sí òye mi,
2. kí o baà lè ní làákàyè,kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ lè kún fún ìmọ̀.
3. Nítorí ẹnu alágbèrè obinrin a máa dùn bí oyin,ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ,
4. ṣugbọn níkẹyìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ á korò bí iwọ,ẹnu rẹ̀ á sì mú bí idà olójú meji.
5. Ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sinu ikú,ìgbésẹ̀ rẹ̀ sì lọ tààrà sinu ibojì.
6. Ó kọ̀ láti rin ọ̀nà ìyè,ọ̀nà rẹ̀ wọ́, kò sì mọ̀.