Ìwé Òwe 4:20-23 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ọmọ mi, fetí sí ọ̀rọ̀ mi,tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun tí mò ń sọ.

21. Má jẹ́ kí wọn rú ọ lójú,fi wọ́n sọ́kàn.

22. Nítorí pé ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó rí wọn,ati ìwòsàn fún gbogbo ẹran ara wọn.

23. Ṣọ́ra pẹlu èrò ọkàn rẹ,nítorí èrò ọkàn ni orísun ìyè.

Ìwé Òwe 4