Ìwé Òwe 31:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Obinrin náà dàbí ọkọ̀ ojú omi oníṣòwò,tí ó ń mú oúnjẹ wálé láti ọ̀nà jíjìn réré.

15. Ìdájí níí tií jí láti wá oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀,ati láti yan iṣẹ́ fún àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀.

16. Bí ó bá rí ilẹ̀ oko, a yẹ̀ ẹ́ wò, a sì rà á,a sì fi èrè iṣẹ́ rẹ̀ gbin ọgbà àjàrà.

17. A fi agbára fún ọ̀já mọ́nú,a sì tẹpá mọ́ṣẹ́.

Ìwé Òwe 31