5. Kò sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun kankan tí ó ń yẹ̀,òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.
6. Má fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,kí ó má baà bá ọ wí,kí o má baà di òpùrọ́.”
7. Nǹkan meji ni mò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ,má ṣe fi wọ́n dù mí kí n tó kú.
8. Jẹ́ kí ìwà èké ati irọ́ pípa jìnnà sí mi,má jẹ́ kí n talaka, má sì jẹ́ kí n di ọlọ́rọ̀,fún mi ní ìwọ̀nba oúnjẹ tí ó tó mi jẹ,
9. kí n má baà yó tán, kí n sẹ́ ọ,kí n wí pé, “Ta ni ń jẹ́ OLUWA?”Má sì jẹ́ kí n tòṣì, kí n má baà jalè,kí n sì kó ẹ̀gbin bá orúkọ Ọlọrun.
10. Má ba iranṣẹ jẹ́ lójú ọ̀gá rẹ̀,kí ó má baà gbé ọ ṣépè, kí o sì di ẹlẹ́bi.
11. Àwọn kan wà tí wọn ń gbé baba wọn ṣépè,tí wọn kò sì súre fún ìyá wọn.