Ìwé Òwe 3:22-25 BIBELI MIMỌ (BM)

22. wọ́n yóo jẹ́ ìyè fún ẹ̀mí rẹ,ati ohun ọ̀ṣọ́ ní ọrùn rẹ.

23. Nígbà náà ni o óo máa rìnláìléwu ati láìkọsẹ̀.

24. Bí o bá jókòó, ẹ̀rù kò ní bà ọ́,bí o bá sùn, oorun yóo máa dùn mọ́ ọ.

25. Má bẹ̀rù àjálù òjijì,tabi ìparun àwọn ẹni ibi,nígbà tí ó bá dé bá ọ,

Ìwé Òwe 3