Ìwé Òwe 26:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Bí yìnyín kò ṣe yẹ ní àkókò ooru,ati òjò ní àkókò ìkórè,bẹ́ẹ̀ ni iyì kò yẹ òmùgọ̀.

2. Bí ológoṣẹ́ tí ń rábàbà kiri,ati bí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń fò ká,bẹ́ẹ̀ ni èpè tí kò nídìí, kì í balẹ̀ síbìkan.

3. Bí pàṣán ti rí lára ẹṣin, tí ìjánu sì rí lẹ́nu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,bẹ́ẹ̀ ni igi rí lẹ́yìn àwọn òmùgọ̀.

4. Má ṣe dá òmùgọ̀ lóhùn gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀,kí ìwọ pàápàá má baà dàbí rẹ̀.

Ìwé Òwe 26