4. Má ṣe làálàá àṣejù láti kó ọrọ̀ jọ,fi ọgbọ́n sẹ́ ara rẹ.
5. Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, owó rẹ lè ti lọ,ó le gúnyẹ̀ẹ́ kí ó fò,bí ìgbà tí ẹyẹ àṣá bá fò lọ.
6. Má ṣe jẹ oúnjẹ ahun,má ní ìfẹ́ sí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀;
7. nítorí ẹni tí ó máa fi ọkàn ṣírò owó oúnjẹ ni.Ó lè máa wí fún ọ pé, “Jẹ, kí o sì mu!”ṣugbọn kò dé inú rẹ̀.
8. O óo pọ gbogbo òkèlè tí o jẹ,gbogbo ọ̀rọ̀ dídùn tí o sọ yóo sì jẹ́ àsọdànù.
9. Má sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀,nítorí yóo gan ọgbọ́n tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ tí o sọ.
10. Má ṣe hú ohun tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ fi pa ààlà láti ìgbà àtijọ́,má sì gba ilẹ̀ ọmọ aláìníbaba;
11. nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára,yóo gba ìjà wọn jà.
12. Fi ọkàn rẹ sí ẹ̀kọ́, kí o sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀.
13. Bá ọmọde wí;bí o bá fi pàṣán nà án, kò ní kú.
14. Bí o bá fi pàṣán nà án,o óo gba ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ ikú.
15. Ọmọ mi, bí o bá gbọ́n,inú mi yóo dùn.
16. N óo láyọ̀ ninu ọkàn minígbà tí o bá ń sọ òtítọ́.
17. Má ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,ṣugbọn máa bẹ̀rù OLUWA lọ́jọ́ gbogbo.
18. Dájúdájú, ọjọ́ ọ̀la rẹ yóo dára,ìrètí rẹ náà kò sì ní já sí òfo.
19. Fetí sí mi, ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,darí ọkàn rẹ sí ọ̀nà títọ́.
20. Má bá àwọn ọ̀mùtí kẹ́gbẹ́;tabi àwọn wọ̀bìà, tí wọn ń jẹ ẹran ní àjẹkì;
21. nítorí pé àwọn ọ̀mùtí ati àwọn wọ̀bìà yóo di talaka,oorun àsùnjù a sì máa sọ eniyan di alákìísà.
22. Gbọ́ ti baba tí ó bí ọ,má sì ṣe pẹ̀gàn ìyá rẹ nígbà tí àgbà bá dé sí i.
23. Ra òtítọ́, má sì tà á,ra ọgbọ́n, ẹ̀kọ́ ati òye pẹlu.
24. Baba olódodo ọmọ yóo láyọ̀ pupọ,inú ẹni tí ó bí ọlọ́gbọ́n ọmọ yóo dùn.