Ìwé Òwe 23:30-34 BIBELI MIMỌ (BM)

30. Àwọn tí wọn máa ń pẹ́ ní ìdí ọtí ni,àwọn tí wọn ń mu ọtí àdàlú.

31. Má jẹ́ kí pípọ́n tí ọtí pọ́n fà ọ́ mọ́ra,nígbà tí ó bá ń ta wínníwínní ninu ife,tí o dà á mu, tí ó lọ geere lọ́nà ọ̀fun.

32. Nígbà tí ó bá yá, á máa buni ṣán bí ejò,oró rẹ̀ á sì dàbí ti ejò paramọ́lẹ̀.

33. Ojú rẹ yóo rí nǹkan àjèjì,ọkàn rẹ á máa ro èròkerò.

34. O óo dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lórí agbami òkun,bí ẹni tí ó sùn lórí òpó ọkọ̀.

Ìwé Òwe 23