Ìwé Òwe 22:7-9 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ọlọ́rọ̀ máa ń jọba lé talaka lórí,ẹni tí ó lọ yá owó sì ni ẹrú ẹni tí ó yá a lówó.

8. Ẹni tí ó bá gbin aiṣododo yóo kórè ìdààmú,pàṣán ibinu rẹ̀ yóo sì parun.

9. Olójú àánú yóo rí ibukun gbà,nítorí pé ó ń fún talaka ninu oúnjẹ rẹ̀.

Ìwé Òwe 22