Ìwé Òwe 20:21-27 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Ogún tí a fi ìkánjú kójọ níbẹ̀rẹ̀,kì í ní ibukun nígbẹ̀yìn.

22. Má sọ pé o fẹ́ fi burúkú san burúkú,gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, yóo sì gbà ọ́.

23. Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA,ìwọ̀n èké kò dára.

24. OLUWA ní ń tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni,eniyan kò lè ní òye ọ̀nà ara rẹ̀.

25. Ronú jinlẹ̀ kí o tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLUWA,kí o má baà kábàámọ̀ rẹ̀.

26. Ọba tó gbọ́n a máa fẹ́ eniyan burúkú dànù,a sì lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.

27. Ẹ̀mí eniyan ni fìtílà OLUWA,tíí máa wá gbogbo kọ́lọ́fín inú rẹ̀ kiri.

Ìwé Òwe 20