Ìwé Òwe 18:9-17 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ẹni tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀,ẹgbẹ́ ni òun ati ẹni tí ń ba nǹkan jẹ́.

10. Orúkọ OLUWA jẹ́ ilé-ìṣọ́ tí ó lágbára,olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì yè.

11. Ohun ìní ọlọ́rọ̀ ni ìlú olódi wọn,lójú wọn, ó dàbí odi ńlá tí ń dáàbò bò wọ́n.

12. Ìgbéraga níí ṣáájú ìparun,ìrẹ̀lẹ̀ níí ṣáájú iyì.

13. Ìwà òmùgọ̀ ni, ìtìjú sì ni, kí eniyan fèsì sí ọ̀rọ̀ kí ó tó gbọ́ ìdí rẹ̀.

14. Eniyan lè farada àìsàn,ṣugbọn ta ló lè farada ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn?

15. Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa fẹ́ ìmọ̀,etí ni ọlọ́gbọ́n fi wá a kiri.

16. Ẹ̀bùn a máa ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn,a sì mú un dé iwájú ẹni gíga.

17. Ẹni tí ó bá kọ́kọ́ rojọ́ níí dàbí ẹni tí ó jàre,títí tí ẹnìkejì yóo fi bi í ní ìbéèrè,

Ìwé Òwe 18