Ìwé Òwe 11:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá kú,ìrètí wọn yóo di asán,bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn tí kò mọ Ọlọrun yóo di òfo.

8. OLUWA a máa gba olódodo lọ́wọ́ ìyọnu,ṣugbọn ẹni ibi a bọ́ sinu wahala.

9. Ẹni tí kò mọ Ọlọrun a máafi ẹnu ba ti aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,ṣugbọn nípa ìmọ̀ a máa gba olódodo sílẹ̀.

10. Nígbà tí nǹkan bá ń dára fún olódodo,gbogbo ará ìlú a máa yọ̀,nígbà tí eniyan burúkú bá kú,gbogbo ará ìlú a sì hó ìhó ayọ̀.

11. Ìre tí olódodo bá sú fún ìlú a máa gbé orúkọ ìlú ga,ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn eniyan burúkú a máa run ìlú.

12. Ẹni tí ó tẹmbẹlu aládùúgbò rẹ̀ kò gbọ́n,ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa pa ẹnu mọ́.

13. Olófòófó a máa tú àṣírí,ṣugbọn ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a máa pa àṣírí mọ́.

14. Níbi tí kò bá ti sí ìtọ́ni, orílẹ̀-èdè a máa ṣubú,ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ọpọlọpọ olùdámọ̀ràn yóo máa gbé ní àìléwu.

15. Ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò yóo rí ìyọnu,ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣe onídùúró yóo wà láìléwu.

16. Obinrin onínúrere gbayì,ṣugbọn ọrọ̀ nìkan ni ìkà yóo ní.

17. Ẹni tí ó ṣoore ṣe é fún ara rẹ̀,ẹni tí ó sì ń ṣìkà ó ń ṣe é fún ara rẹ̀.

Ìwé Òwe 11