Ìwé Òwe 11:22-28 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ni obinrin tí ó lẹ́wà tí kò ní làákàyè.

23. Ìfẹ́ ọkàn olódodo a máa yọrí sí rere,ṣugbọn ìrètí eniyan burúkú a máa já sí ibinu.

24. Ẹnìkan wà tíí máa ṣe ìtọrẹ àánú káàkiri,sibẹsibẹ àníkún ni ó ń ní,ẹnìkan sì wà tí ó háwọ́,sibẹsibẹ aláìní ni.

25. Ẹni tí ó bá lawọ́ yóo máa ní àníkún,ẹni tí ó bá jẹ́ kí ọkàn ẹlòmíràn balẹ̀,ọkàn tirẹ̀ náà yóo balẹ̀.

26. Ẹni tí ó bá ń kó oúnjẹ pamọ́, yóo gba ègún sórí,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ta oúnjẹ, yóo rí ibukun gbà.

27. Ẹni tí ó bá ń wá ire, yóo rí ojurere,ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ibi, ibi yóo bá a.

28. Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóo rẹ̀ dànù bí òdòdó,ṣugbọn olódodo yóo rú bí ewé tútù.

Ìwé Òwe 11