Ìwé Oníwàásù 3:3-5 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Àkókò pípa wà, àkókò wíwòsàn sì wà,àkókò wíwó lulẹ̀ wà, àkókò kíkọ́ sì wà.

4. Àkókò ẹkún wà, àkókò ẹ̀rín sì wà;àkókò ọ̀fọ̀ wà, àkókò ijó sì wà.

5. Àkókò fífọ́n òkúta ká wà, àkókò kíkó òkúta jọ sì wà;àkókò ìkónimọ́ra wà, àkókò àìkónimọ́ra sì wà.

Ìwé Oníwàásù 3