Ìwé Oníwàásù 10:8-12 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ẹni tí ó gbẹ́ kòtò ni yóo jìn sinu rẹ̀,ẹni tí ó bá já ọgbà wọlé ni ejò yóo bùjẹ.

9. Ẹni tí ó bá ń fọ́ òkúta, ni òkúta í pa lára;ẹni tí ó bá ń la igi, ni igi í ṣe ní jamba.

10. Ẹni tí kò bá pọ́n àáké rẹ̀ kí ó mú,yóo lo agbára pupọ bí ó bá fẹ́ lò ó,ṣugbọn ọgbọ́n a máa ranni lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí.

11. Lẹ́yìn tí ejò bá ti buni jẹ tán,kò ṣàǹfààní mọ́ kí á máa pọfọ̀ sí ejò.

12. Ọ̀rọ̀ ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa bu iyì kún un,ṣugbọn ẹnu òmùgọ̀ ni yóo pa á.

Ìwé Oníwàásù 10