9. Ó dá mi lóhùn, ó ní: “Ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli ati ti Juda pọ̀jù. Ilẹ̀ náà kún fún ìpànìyàn, ìlú yìí sì kún fún ìwà àìṣẹ̀tọ́. Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA ti kọ ilẹ̀ yìí sílẹ̀, kò sì rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ninu rẹ̀.’
10. N kò ní mójú fo ọ̀rọ̀ wọn, n kò sì ní ṣàánú wọn. N óo da ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wọn lé wọn lórí.”
11. Mo bá gbọ́ tí ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó sì ní àpótí ìkọ̀wé lẹ́gbẹ̀ẹ́, ń jábọ̀ pé, “Mo ti ṣe bí o ti pàṣẹ fún mi.”