Isikiẹli 9:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, Ọlọrun kígbe sí mi létí, ó ní, “Ẹ súnmọ́bí, ẹ̀yin tí ẹ óo pa ìlú yìí run, kí olukuluku mú nǹkan ìjà rẹ̀ lọ́wọ́.”

2. Wò ó! Mo bá rí àwọn ọkunrin mẹfa kan tí wọn ń bọ̀ láti ẹnu ọ̀nà òkè tí ó kọjú sí ìhà àríwá. Olukuluku mú ohun ìjà tí ó fẹ́ fi pa eniyan lọ́wọ́. Ọkunrin kan wà láàrin wọn tí ó wọ aṣọ funfun, ó sì ní àpótí ìkọ̀wé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́. Wọ́n wọlé, wọ́n dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ idẹ.

3. Ògo Ọlọrun Israẹli ti gbéra kúrò lórí àwọn Kerubu tí ó wà, ó dúró sí àbáwọlé. Ó ké sí ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun náà, tí ó sì ní àpótí ìkọ̀wé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́.

4. OLUWA bá sọ fún un pé, “Lọ káàkiri ìlú Jerusalẹmu, kí o fi àmì sí iwájú àwọn eniyan tí wọ́n bá ń kẹ́dùn, tí gbogbo nǹkan ìríra tí àwọn eniyan ń ṣe láàrin ìlú náà sì dùn wọ́n dọ́kàn.”

Isikiẹli 9