3. Ọba nìkan ni ó lè jókòó níbẹ̀ láti jẹun níwájú OLUWA. Yóo gba ẹnu ọ̀nà ìloro wọlé, ibẹ̀ náà ni yóo sì gbà jáde.”
4. Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà mú mi gba ẹnu ọ̀nà ìhà àríwá wá siwaju tẹmpili; mo sì rí i tí ìtànṣán ògo OLUWA kún inú tẹmpili, mo bá dojúbolẹ̀.
5. OLUWA bá sọ fún mi pé: “Ìwọ ọmọ eniyan, ṣe akiyesi dáradára, ya ojú rẹ, kí o sì fi etí sílẹ̀ kí o gbọ́ gbogbo ohun tí n óo sọ fún ọ nípa àṣẹ ati àwọn òfin tí ó jẹ mọ́ tẹmpili OLUWA. Ṣe akiyesi àwọn eniyan tí a lè gbà láàyè kí wọ́n wọ inú tẹmpili ati àwọn tí kò gbọdọ̀ wọlé.
6. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn olóríkunkun, pé OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ dáwọ́ àwọn nǹkan ìríra tí ẹ̀ ń ṣe dúró.
7. Nígbà tí ẹ̀ ń gbà fún àwọn àlejò, tí a kò kọ nílà abẹ́, ati ti ọkàn, láti máa wọ ibi mímọ́ mi nígbà tí ẹ bá ń fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi, ibi mímọ́ mi ni ẹ̀ ń sọ di aláìmọ́. Ẹ ti fi àwọn ohun ìríra yín ba majẹmu mi jẹ́.