1. OLUWA Ọlọrun ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá Gogu wí, sọ fún un pé OLUWA Ọlọrun ní: ‘Mo lòdì sí ọ́, ìwọ Gogu, ìwọ tí o jẹ́ olórí Meṣeki ati Tubali.
2. N óo yí ọ pada, n óo lé ọ siwaju, n óo mú ọ wá láti òpin ìhà àríwá, o óo wá dojú kọ àwọn òkè Israẹli.
3. Lẹ́yìn náà, n óo gbọn ọrun rẹ dànù lọ́wọ́ òsì rẹ; n óo sì gbọn ọfà bọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ.
4. Ìwọ, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ, ati àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo kú lórí àwọn òkè Israẹli. N óo fi yín ṣe oúnjẹ fún oniruuru àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko burúkú.
5. Ninu pápá tí ó tẹ́jú ni ẹ óo kú sí; èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
6. N óo rọ òjò iná lé Magogu lórí, ati àwọn tí wọn ń gbé láìléwu ní etí òkun, wọn yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.
7. N óo sọ orúkọ mímọ́ mi di mímọ̀ láàrin àwọn eniyan mi àwọn ọmọ Israẹli, n kò ní jẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.’ ”
8. OLUWA Ọlọrun ní, “Ẹ wò ó! Ọjọ́ tí mo ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bọ̀, yóo dé.