23. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
24. “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Israẹli tí ó ti di aṣálẹ̀ wọnyi, ń wí pé, ‘Ẹnìkan péré ni Abrahamu, bẹ́ẹ̀ ó sì gba ilẹ̀ yìí. Àwa pọ̀ ní tiwa, nítorí náà, a ti fi ilẹ̀ yìí fún wa, kí á gbà á ló kù.’
25. “Nítorí náà, wí fún wọn pé OLUWA Ọlọrun ní, Ẹ̀ ń jẹ ẹran pẹlu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ̀ ń bọ oriṣa, ẹ sì ń pa eniyan, ṣé ẹ rò pé ilẹ̀ náà yóo di tiyín?
26. Idà ni ó kù tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé; ẹ̀ ń ṣe ohun ìríra, ẹ̀ ń bá iyawo ara yín lòpọ̀, ẹ sì rò pé ẹ óo jogún ilẹ̀ yìí?
27. “Mo fi ara mi búra, ogun ni yóo pa àwọn tí ń gbé àwọn ìlú tí ó ti di ahoro. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo jẹ́ kí ẹranko burúkú pa àwọn tí wọ́n wà ninu pápá jẹ, àjàkálẹ̀ àrùn yóo sì pa àwọn tí wọ́n sápamọ́ sí ibi ààbò ati ninu ihò àpáta.
28. N óo sọ ilẹ̀ yìí di ahoro ati aṣálẹ̀. Agbára tí ó ń gbéraga sí yóo dópin. Àwọn òkè Israẹli yóo di ahoro tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní gba ibẹ̀ kọjá.