Isikiẹli 31:14-16 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀ kí igi mìíràn tí ó bá wà lẹ́bàá omi náà má baà ga fíofío mọ́, tabi kí orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu ní ojú ọ̀run. Kò sì ní sí igi tí ń fa omi, tí yóo ga tó ọ; nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kú, tí wọn óo sì lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun ilẹ̀ bí àwọn alààyè eniyan tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú.”

15. OLUWA Ọlọrun ní: “Nígbà tí ó bá wọ isà òkú ọ̀gbun ilẹ̀ pàápàá, n óo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, n óo sé àwọn odò n óo sì ti orísun omi ìsàlẹ̀ ilẹ̀ nítorí rẹ̀, òkùnkùn óo bo Lẹbanoni, gbogbo igi inú igbó yóo gbẹ nítorí rẹ̀.

16. Ìró wíwó rẹ̀ yóo mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì. Nígbà tí mo bá wó o lulẹ̀ tí mo bá sọ ọ́ sinu isà òkú pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú; gbogbo àwọn igi Edẹni, ati àwọn igi tí wọ́n dára jù ní Lẹbanoni, gbogbo àwọn igi tí ń rí omi mu lábẹ́ ilẹ̀ ni ara yóo tù.

Isikiẹli 31