Isikiẹli 3:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ Eniyan, jẹ ohun tí a fún ọ; jẹ ìwé tí a ká yìí, kí o sì lọ bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.”

2. Mo bá la ẹnu, ó sì fún mi ní ìwé náà jẹ.

3. Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, jẹ ìwé tí a ká, tí mo fún ọ yìí, kí o sì yó.” Mo bá jẹ ẹ́, ó sì dùn bí oyin lẹ́nu mi.

4. Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, lọ bá àwọn ọmọ Israẹli kí o sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn.

5. Kì í sá ṣe àwọn tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí ó ṣòro gbọ́, ni mo rán ọ sí, àwọn ọmọ ilé Israẹli ni.

6. N kò rán ọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń sọ èdè mìíràn tí yóo ṣòro fún ọ láti gbọ́. Dájúdájú, bí ó bá jẹ́ irú wọn ni mo rán ọ sí, wọn ìbá gbọ́ tìrẹ.

7. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò ní gbọ́ tìrẹ, nítorí pé wọn kò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Olóríkunkun ati ọlọ́kàn líle ni gbogbo wọn.

8. Mo ti mú kí ojú rẹ le sí tiwọn.

Isikiẹli 3