Isikiẹli 23:16-23 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Bí ó ti rí wọn, wọ́n wọ̀ ọ́ lójú, ó bá rán ikọ̀ sí wọn ní ilẹ̀ Kalidea.

17. Àwọn ará Babiloni bá tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bá a ṣeré ìfẹ́ lórí ibùsùn rẹ̀, wọ́n sì fi ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn bà á jẹ́. Nígbà tí wọ́n bà á jẹ́ tán, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn pẹlu ìríra.

18. Nígbà tí ó ń ṣe àgbèrè ní gbangba, tí ó sì tú ara rẹ̀ sí ìhòòhò, mo yipada kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu ìríra, bí mo ti yipada kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

19. Sibẹ ó tún fi kún ìwà àgbèrè rẹ̀, nígbà tí ó ranti àgbèrè ìgbà èwe rẹ̀ ní ilẹ̀ Ijipti.

20. Ó kún fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fún àwọn ọkunrin tí ojú ara wọn dàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, nǹkan ọkunrin wọn sì dàbí ti ẹṣin.”

21. O tún fẹ́ láti máa ṣe ìṣekúṣe tí o ṣe nígbà èwe rẹ, tí àwọn ọkunrin Ijipti ń dì mọ́ ọ lẹ́gbẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ń fi ọwọ́ fún ọ ní ọmú ọmọge.

22. Nítorí náà, Oholiba, OLUWA Ọlọrun ní, “Mo ṣetán tí n óo gbé àwọn olùfẹ́ rẹ dìde, àwọn tí o kọ̀ sílẹ̀ nítorí ìríra. N óo mú wọn dojú kọ ọ́ ní gbogbo ọ̀nà:

23. àwọn ará Babiloni ati gbogbo àwọn ará Kalidea láti Pekodi, ati Ṣoa ati Koa, pẹlu gbogbo àwọn ará Asiria: àwọn ọdọmọkunrin tí ojú wọn fanimọ́ra, àwọn gomina, ati àwọn ọ̀gágun, tí gbogbo wọn jẹ́ olórí ogun, tí wọ́n sì ń gun ẹṣin.

Isikiẹli 23