Isikiẹli 21:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní,

2. “Ìwọ ọmọ eniyan, kọjú sí Jerusalẹmu kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ibi mímọ́ Israẹli. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli.

3. Sọ fún ilẹ̀ náà pé OLUWA ní, ‘Wò ó, mo ti dojú kọ ọ́, n óo yọ idà mi ninu àkọ̀ rẹ̀, n óo sì pa àwọn eniyan inú rẹ: ati àwọn eniyan rere ati àwọn eniyan burúkú.

Isikiẹli 21