Isikiẹli 20:29-39 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Mo bi wọ́n léèrè pé irú ibi pẹpẹ ìrúbọ wo ni ẹ tilẹ̀ ń lọ ríì? Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní Bama títí di òní.

30. Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ṣé ẹ óo máa ba ara yín jẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba yín, ẹ óo sì máa ṣìnà tẹ̀lé àwọn nǹkan ìríra wọn?

31. Ẹ̀ ń rú àwọn ẹbọ yín, ẹ sì ń fi àwọn ọmọkunrin yín rú ẹbọ sísun, ẹ sì ti fi oriṣa bíbọ ba ara yín jẹ́ títí di òní. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ṣé ẹ óo tún máa wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ mi? Mo fi ara mi búra pé, ẹ kò ní rídìí ọ̀rọ̀ kankan lọ́dọ̀ mi.

32. Èrò ọkàn yín kò ní ṣẹ: ẹ̀ ń gbèrò ati dàbí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ati àwọn ẹ̀yà tí ó wà ní agbègbè yín, kí ẹ máa bọ igi ati òkúta.

33. “Mo fi ara mi búra, dájúdájú, tipátipá, pẹlu ibinu ati ọwọ́ líle ni n óo fi jọba lórí yín.

34. N óo ko yín jáde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo ko yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti fi tipátipá fọ́n yín ká sí, pẹlu ọwọ́ líle, ati ibinu.

35. N óo ko yín lọ sinu aṣálẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, níbẹ̀ ni n óo ti dájọ́ yín lojukooju.

36. Bí mo ṣe dájọ́ àwọn baba ńlá yín ní aṣálẹ̀ ilẹ̀ Ijipti ni n óo dájọ́ yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

37. “N óo mú kí ẹ gba abẹ́ ọ̀pá mi kọjá, n óo sì mu yín wá sí abẹ́ ìdè majẹmu.

38. N óo ṣa àwọn ọlọ̀tẹ̀ ati àwọn tí ń ṣe oríkunkun sí mi kúrò láàrin yín. N óo mú wọn kúrò ní ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò, ṣugbọn wọn kò ní dé ilẹ̀ Israẹli. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”

39. Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, OLUWA Ọlọrun ní, “Kí olukuluku yín lọ máa bọ oriṣa rẹ̀ láti ìsinsìnyìí lọ, bí ẹ kò bá fẹ́ gbọ́ tèmi, ṣugbọn ẹ kò ní fi ẹbọ ati oriṣa yín ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́.

Isikiẹli 20