Isikiẹli 18:31-32 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Ẹ kọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín tí ẹ̀ ń dá sí mi sílẹ̀. Ẹ wá ọkàn tuntun ati ẹ̀mí tuntun fún ara yín. Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ kú, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli?

32. N kò ní inú dídùn sí ikú ẹnikẹ́ni, nítorí náà, ẹ yipada kí ẹ lè yè. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Isikiẹli 18