Isikiẹli 11:17-23 BIBELI MIMỌ (BM)

17. “Nítorí náà, wí fún wọn pé èmi, ‘OLUWA Ọlọrun ní n óo kó wọn jọ láti ààrin àwọn ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo fọ́n wọn ká sí, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli.’

18. Nígbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọn óo ṣa gbogbo ohun ẹ̀gbin ati ìríra rẹ̀ kúrò ninu rẹ̀.

19. Ó ní, mo sọ pé, n óo fún wọn ní ọkàn kan, n óo fi ẹ̀mí titun sí wọn ninu. N óo yọ ọkàn òkúta kúrò láyà wọn, n óo sì fún wọn ní ọkàn ẹran;

20. kí wọ́n lè máa rìn ninu ìlànà mi, kí wọ́n sì lè máa pa òfin mi mọ́. Wọn óo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn.

21. Ṣugbọn n óo fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn tí ọkàn wọn ń fà sí àwọn ohun ẹ̀gbin ati ìríra. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

22. Lẹ́yìn náà, àwọn Kerubu bá gbéra, wọ́n fò, pẹlu àgbá, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn; ìtànṣán ògo OLUWA Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn.

23. Ògo OLUWA gbéra kúrò láàrin ìlú náà, ó sì dúró sórí òkè tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn ìlú náà.

Isikiẹli 11