7. Ọ̀dọ́ Aguntan náà bá wá, ó sì gba ìwé náà ní ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́.
8. Nígbà tí ó gbà á, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn mẹrinlelogun náà dojúbolẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́ Aguntan yìí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn mú hapu kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́, ati àwo wúrà kéékèèké, tí ó kún fún turari. Turari yìí ni adura àwọn eniyan Ọlọrun, àwọn onigbagbọ.
9. Wọ́n wá ń kọ orin titun kan, pé,“Ìwọ ni ó tọ́ sí láti gba ìwé náà,ati láti tú èdìdì ara rẹ̀.Nítorí wọ́n pa ọ́,o sì ti fi ẹ̀jẹ̀ rẹ bá Ọlọrun ṣe ìràpadà eniyan,láti inú gbogbo ẹ̀yà,ati gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè.