8. Nítorí èyí, ní ọjọ́ kan náà ni oríṣìíríṣìí òfò yóo dé bá a,ati àjàkálẹ̀ àrùn, ati ọ̀fọ̀, ati ìyàn.Iná yóo tún jó o ní àjórun,nítorí alágbára ni Oluwa Ọlọrun tí ó ti ń ṣe ìdájọ́ fún un.”
9. Àwọn ọba ayé ati àwọn tí wọ́n ti bá a ṣe àgbèrè, tí wọ́n ti ń bá a jayé yóo sunkún, wọn óo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí nígbà tí wọ́n bá rí èéfín iná tí ń jó o.
10. Wọn óo dúró ní òkèèrè nítorí ẹ̀rù tí yóo máa bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀. Wọn óo sọ pé,“Ó ṣe! Ó ṣe fún ọ! Ìlú ńlá,Babiloni ìlú alágbára!Nítorí ní wakati kan ni ìparun dé bá ọ.”
11. Àwọn oníṣòwò ayé yóo sunkún, wọn yóo ṣọ̀fọ̀ lé e lórí, nítorí wọn kò rí ẹni ra ọjà wọn mọ́; àwọn nǹkan bíi:
12. Wúrà, fadaka, òkúta iyebíye, oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀, aṣọ funfun ati àlàárì, ati sányán ati aṣọ pupa; oríṣìíríṣìí pákó, ati àwọn ohun èèlò tí a fi eyín erin, igi iyebíye, idẹ, irin, ati òkúta ṣe;